O. Daf 64 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 64 Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. 1 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá. 2 Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà, wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò. 4 Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀: wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù. 5 Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú, wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?” 6 Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé, “A wa ti parí èrò tí a gbà tán” lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè. 7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà; wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì. 8 Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n, Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn. 9 Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe. 10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀. Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.