O. Daf 6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 6 Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. 1 Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ 2 Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ; Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira. 3 Ọkàn mi wà nínú ìrora. Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó? 4 Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí; gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í. 5 Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú. Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú? 6 Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé. 7 Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́; wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi. 8 Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi, nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi. 9 Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi. 10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú; wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.