Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 55 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 55
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.

1 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run, Má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:

2 Gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn. Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.

3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni, nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú; nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi, wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.

4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú; ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.

5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi; ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.

6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà! Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.

7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré, kí ń sì dúró sí aginjù;

8 Èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò, jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”

9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú, nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.

10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri; ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.

11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀; ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.

12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fi ara mọ́ ọn; tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi, èmi ìbá sápamọ́ fún un.

13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,

14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀, bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.

15 Kí ikú kí ó dé bá wọn, Kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú, Jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà, nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; Olúwa yóò sì gbà mí.

17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú, o sì gbọ́ ohùn mi.

18 Ó rà mí padà láìléwu kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.

19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela. Nítorí tí wọn kò ní àyípadà, tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.

20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀; ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.

21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́, ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

22 Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa yóò sì mú ọ dúró; òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.

23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun; Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn, kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn. Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan