O. Daf 52 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 52 Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.” 1 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin? Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo, ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run? 2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun; ó dàbí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn. 3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ. 4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn! 5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ, yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela. 6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé, 7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé, ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.” 8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run; Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé. 9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe; èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí orúkọ rẹ dára. Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.