O. Daf 46 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 46 Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin. 1 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú. 2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí, tí òkè sì ṣubú sínú Òkun. 3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela. 4 Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn, ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé. 5 Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀: Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀. 6 Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú, ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀. 7 Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa, Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa. 8 Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa irú ahoro tí ó ṣe ní ayé. 9 O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná 10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run. A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè A ó gbé mi ga ní ayé. 11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.