Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 36 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 36
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa

1 Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé; Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.

2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.

3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn; wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;

4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn: wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.

5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run, òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.

6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá; ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.

7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.

8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.

9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!

11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi, kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.

12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí: a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan