Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 30 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 30
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.

1 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa, nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.

2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́ ìwọ sì ti wò mí sàn.

3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú, mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.

4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.

5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé, “a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”

7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa, ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára; ìwọ pa ojú rẹ mọ́, àyà sì fò mí.

8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é; àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:

9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi, nínú lílọ sí ihò mi? Eruku yóò a yìn ọ́ bí? Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?

10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi; ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,

12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́. Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan