O. Daf 3 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 3 Saamu ti Dafidi. Nígbà ti ó sá fún ọmọ rẹ̀ Absalomu. 1 Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó! 2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela. 3 Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, Olúwa; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè. 4 Olúwa ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. 5 Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró. 6 Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká. 7 Dìde, Olúwa! Gbà mí, Ọlọ́run mi! Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n; kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú. 8 Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá. Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.