Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 26 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 26
Ti Dafidi.

1 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi, mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.

2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò, dán àyà àti ọkàn mi wò;

3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi, èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;

5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.

6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.

7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́, èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé, àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.

9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,

10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́; rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.

12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú; nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan