O. Daf 24 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 24 Ti Dafidi. Saamu. 1 Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀; 2 Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi. 3 Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀? 4 Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké. 5 Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀. 6 Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela. 7 Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé. 8 Ta ni ọba ògo náà? Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le, Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun. 9 Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá. 10 Ta ni Ọba ògo náà? Olúwa àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.