O. Daf 23 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 23 Saamu ti Dafidi. 1 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní. 2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́; 3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. 4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn Láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ wọ́n ń tù mí nínú. 5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi; ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. 6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa títí láéláé. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.