Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 2 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 2

1 Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀, àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?

2 Àwọn ọba ayé péjọpọ̀ àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀ sí Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.

3 Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já, kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

4 Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín; Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5 Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀ yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,

6 “Èmi ti fi ọba mi sí ipò lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

7 Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa: Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí, èmi ti di baba rẹ.

8 Béèrè lọ́wọ́ mi, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ, òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.

9 Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n; ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.

11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú, kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín, nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan