Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 149 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 149

1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa. Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

2 Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn.

3 Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

4 Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé

5 Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀ kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

6 Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.

7 Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè, àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,

8 Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ọlọ́lá wọn.

9 Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan