O. Daf 148 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 148 1 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá, Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga. 2 Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀ 3 Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀. 4 Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run. 5 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn 6 Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já. 7 Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú Òkun 8 Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; 9 Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé, igi eléso àti gbogbo igi kedari, 10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́: 11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé, 12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé. 13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run 14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.