Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 137 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 137

1 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

2 Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò, tí ó wà láàrín rẹ̀.

3 Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé; ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.

4 Àwa ó ti ṣe kọ orin Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì

5 Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.

6 Bí èmi kò bá rántí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo.

7 Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu, lára àwọn ọmọ Edomu, àwọn ẹni tí ń wí pé, “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”

8 Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun; ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ bí ìwọ ti rò sí wa.

9 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan