O. Daf 131 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 131 Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. 1 Olúwa àyà mi kò gbéga, bẹ́ẹ̀ ni ojú mi kò gbé sókè: bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi ọwọ́ mi lé ọ̀ràn ńlá, tàbí lé ohun tí ó ga jù mí lọ 2 Nítòótọ́ èmi mú ọkàn mi sinmi, mo sì mú un dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ tí a ti ọwọ́ ìyá rẹ̀ gbà ní ẹnu ọmú: ọkàn mi rí gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí a já ní ẹnu ọmú. 3 Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti láéláé. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.