Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 127 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 127
Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.

1 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni; bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.

2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá; bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.

3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa: ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.

4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe

5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn; ojú kì yóò tì wọ́n, ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan