O. Daf 124 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 124 Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. 1 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa” ni kí Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí; 2 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,” Nígbà tí àwọn ènìyàn dúró sí wa: 3 Nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa 4 Nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀ 5 Nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa. 6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n bí ohun ọdẹ fún eyín wọn. 7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ; okùn já àwa sì yọ. 8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa, tí ó dá ọ̀run òun ayé. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.