O. Daf 114 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 114 1 Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè 2 Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba. 3 Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn. 4 Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn. 5 Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn? 6 Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn? 7 Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú Olúwa; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu 8 tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.