O. Daf 110 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 110 Ti Dafidi. Saamu. 1 Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” 2 Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ. 3 Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ. 4 Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.” 5 Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀ 6 Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí, yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara; yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò. 7 Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà: nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.