Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 105 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 105

1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀: Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;

2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i; sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.

3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀: Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.

4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀; wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.

5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,

6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.

7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa: ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.

8 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,

9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.

10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:

11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”

12 Nígbà tí wọn kéré níye, wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀

13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan sí èkejì.

14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tiwọn:

15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”

16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;

17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.

18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀ a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin

19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.

20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀ àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀

21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀ aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,

22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.

23 Israẹli wá sí Ejibiti; Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.

24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i ó sì mú wọn lágbára jù àwọn ọ̀tá wọn lọ

25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Aaroni tí ó ti yàn

27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.

28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó pa ẹja wọn.

30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá, èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.

31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde, ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn

32 Ó sọ òjò di yìnyín, àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;

33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.

34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé, àti kòkòrò ní àìníye,

35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn, wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run

36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn, ààyò gbogbo ipá wọn.

37 Ó mú Israẹli jáde ti òun ti fàdákà àti wúrà, nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.

38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ, nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.

39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí, àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́

40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá, ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.

41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde; gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.

42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀ àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.

43 Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀

44 Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà, wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45 Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan