O. Daf 103 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 103 Ti Dafidi. 1 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́. 2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀ 3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn, 4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé, 5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì. 6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ni lára. 7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli; 8 Olúwa ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. 9 Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé; 10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa. 11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. 12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa. 13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀; 14 Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá. 15 Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó; 16 Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́. 17 Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ 18 Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n. 19 Olúwa ti pèsè ìtẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀run, ìjọba rẹ̀ ní ó sì borí ohun gbogbo. 20 Yin Olúwa, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, tí ó ní ipá, tí ó pa òfin ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ 21 Yin Olúwa, ẹ̀yin ogun ọ̀run rẹ̀ gbogbo, ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. 22 Yin Olúwa, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ní ibi gbogbo ìjọba rẹ̀. Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.