Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Oniwaasu 4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ìnilára, làálàá, àti àìlọ́rẹ̀ẹ́

1 Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára, wọn kò sì ní olùtùnú kankan.

2 Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó sàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láààyè lọ.

3 Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.

4 Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.

5 Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.

6 Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà, àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.

7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn:

8 Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà; kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo, síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá, àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà asán ni iṣẹ́ òsì!

9 Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn:

10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!

11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.


Asán ni ipò gíga

13 Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn,

14 Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀.

15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.

16 Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan