Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Numeri 25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Moabu tan Israẹli jẹ

1 Nígbà tí àwọn Israẹli dúró ní Ṣittimu, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Moabu,

2 tí ó pè wọ́n sí ibi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn.

3 Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.

4 Olúwa sọ fún Mose pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”

5 Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.”

6 Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé.

7 Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

8 Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró;

9 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá-méjìlá. (24,000).

10 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,

11 “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.

12 Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.

13 Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”

14 Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni.

15 Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani.

16 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,

17 “Ka àwọn ará Midiani sí ọ̀tá, kí o sì pa wọ́n,

18 nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan