Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Mika 4 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Òkè Olúwa

1 Ní ọjọ́ ìkẹyìn a ó fi òkè ilé Olúwa lélẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ̀ sínú rẹ̀.

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu Òun yóò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.

3 Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

4 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n, nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.

5 Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.


Èrò Olúwa

6 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò kó àwọn arọ jọ; èmi yóò sì ṣà àwọn tí a lé kúrò ní ìlú jọ, àti àwọn ẹni tí èmi ti pọ́n lójú.

7 Èmi yóò dá àwọn arọ sí fún èyí tókù, èmi yóò sì sọ àwọn tí a lé kúrò ní ìlú di orílẹ̀-èdè alágbára. Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí wọn ní òkè ńlá Sioni láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

8 Ní ti ìwọ, ilé ìṣọ́ agbo àgùntàn, odi alágbára ọmọbìnrin Sioni, a ó mú ìjọba ìṣáájú padà bọ̀ sípò fún un yín; ìjọba yóò sì wà sí ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”

9 Kí ni ìwọ ha ń kígbe sókè sí nísinsin yìí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ní ọba bí? Àwọn ìgbìmọ̀ rẹ ṣègbé bí? Nítorí ìrora ti dì ọ́ mú bí obìnrin tí ń rọbí.

10 Máa yí síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ìrora, ìwọ obìnrin Sioni, bí ẹni tí ń rọbí, nítorí nísinsin yìí ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì máa gbé inú igbó. Ìwọ yóò lọ sí Babeli; níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì ti rí ìgbàlà. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.

11 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè kó ara wọn jọ sí ọ. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sọ ọ́ di àìmọ́, Ẹ jẹ́ kí ojú wa kí ó wo Sioni!”

12 Ṣùgbọ́n wọn kò mọ èrò inú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni òye ìmọ̀ rẹ̀ kò yé wọn, nítorí ó ti kó wọn jọ bí i ìtí sínú ìpakà.

13 “Dìde, kí ó sì máa pa ọkà ìwọ ọmọbìnrin Sioni, nítorí èmi yóò sọ ìwo rẹ̀ di irin, èmi yóò sì sọ pátákò rẹ̀ di idẹ ìwọ yóò run ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pátápátá.” Èmi yóò sì ya èrè wọn sọ́tọ̀ fún Olúwa àti ọrọ̀ wọn sí Olúwa gbogbo ayé.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan