Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Joṣua 12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Orúkọ àwọn ọba tí a ṣẹ́gun

1 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé Òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

2 Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín Àfonífojì náà dé Odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.

3 Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.

4 Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.

5 Ó ṣe àkóso ní orí Òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni.

6 Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.

7 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni sí Òkè Halaki, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:

8 ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi):

9 Ọba Jeriko ọ̀kan Ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli) ọ̀kan

10 Ọba Jerusalẹmu ọ̀kan ọba Hebroni ọ̀kan

11 Ọba Jarmatu ọ̀kan ọba Lakiṣi ọ̀kan

12 Ọba Egloni ọ̀kan ọba Geseri ọ̀kan

13 Ọba Debiri ọ̀kan ọba Gederi ọ̀kan

14 Ọba Horma ọ̀kan ọba Aradi ọ̀kan

15 Ọba Libina ọ̀kan ọba Adullamu ọ̀kan

16 Ọba Makkeda ọ̀kan ọba Beteli ọ̀kan

17 Ọba Tapua ọ̀kan ọba Heferi ọ̀kan

18 Ọba Afeki ọ̀kan ọba Laṣaroni ọ̀kan

19 Ọba Madoni ọ̀kan ọba Hasori ọ̀kan

20 Ọba Ṣimroni-Meroni ọ̀kan ọba Akṣafu ọ̀kan

21 Ọba Taanaki ọ̀kan ọba Megido ọ̀kan

22 Ọba Kedeṣi ọ̀kan ọba Jokneamu ni Karmeli ọ̀kan

23 Ọba Dori (ní Nafoti Dori) ọ̀kan ọba Goyimu ní Gilgali ọ̀kan

24 Ọba Tirsa ọ̀kan gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan