Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Jobu 6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ìdáhùn Jobu

1 Jobu sì dáhùn ó si wí pé:

2 “Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n, kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!

3 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn Òkun lọ: nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé

4 Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú, oró èyí tí ọkàn mi mú; ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.

5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko, tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?

6 A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀, tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?

7 Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò, òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.

8 “Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà; àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.

9 Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run, tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

10 Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀, àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí: nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11 “Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí? Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?

12 Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí? Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?

13 Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi: ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

14 “Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?

15 Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.

16 Tí ó dúdú nítorí omi dídì, àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.

17 Nígbàkúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ, nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

18 Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.

19 Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi, àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.

20 Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e; wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.

21 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn; ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.

22 Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá, tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?

23 Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni, tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?

24 “Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́ kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.

25 Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?

26 Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.

27 Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28 “Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín. Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé: Ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.

29 Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀; àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.

30 Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi? Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan