Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Jobu 36 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Elihu sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:

2 “Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́, nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.

3 Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.

4 Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

5 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

6 Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí, ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7 Òun kì í mú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8 Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9 Nígbà náà ni ó ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga wọn.

10 Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedédé.

11 Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀rùn, àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12 Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.

13 “Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní ayé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá wọ́n wí.

14 Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ní àárín àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà.

15 Òun gba òtòṣì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínú ìnira wọn.

16 “Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó fa wọn yọ láti inú ìhágágá sí ibi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀, ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.

17 Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.

18 Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ; láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.

19 Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbí ipa agbára rẹ?

20 Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.

21 Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú; Nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

22 “Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?

23 Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un, tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?

24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti ènìyàn ni yín nínú orin.

25 Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i; ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè,

26 Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,

28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.

29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?

30 Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká ó sì bo ìsàlẹ̀ Òkun mọ́lẹ̀.

31 Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn; ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ó sì rán an sí ẹni olódì.

33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní; ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan