Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Jobu 28 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye Jobu

1 Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.

2 Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.

3 Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí ìṣúra láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.

4 Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.

5 Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná

6 Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.

7 Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí;

8 Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.

9 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

10 Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

11 Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

12 Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?

13 Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

14 Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.”

15 A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

16 A kò le è fi wúrà ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e.

17 Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀.

18 A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.

19 Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

20 Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?

21 A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

22 Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

23 Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé.

24 Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

25 Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi.

26 Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

27 Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

28 Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan