Jobu 25 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníÌdáhùn Bilidadi 1 Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé: 2 “Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run. 3 Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí? 4 Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́? 5 Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀, 6 kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!” |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.