Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Jobu 12 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ìdáhùn Jobu

1 Jobu sì dáhùn, ó sì wí pé:

2 “Kò sí àní àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!

3 Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: èmi kò kéré sí i yín: àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?

4 “Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn: à ń fi olóòtítọ́ ẹni ìdúró ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5 Ó rọrùn fún ènìyàn láti fi ìbànújẹ́ ẹlòmíràn ṣe ẹlẹ́yà, gẹ́gẹ́ bí ìpín àwọn ẹni tí ẹsẹ̀ wọn ṣetán láti yọ̀.

6 Àgọ́ àwọn ìgárá ọlọ́ṣà wá láìní ìbẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.

7 “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

8 Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú Òkun yóò sì sọ fún ọ.

9 Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?

10 Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.

11 Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?

12 Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún, àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.

13 “Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára: Òun ló ni ìmọ̀ àti òye.

14 Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́; Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.

15 Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.

16 Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun; Ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.

17 Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò, A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18 Ó tú ìdè ọba, Ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

19 Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò, Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

20 Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò, Ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.

21 Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá, Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.

22 Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá, Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.

23 Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n; Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.

24 Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé, A sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.

25 Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀, Òun a sì máa mú ìrìn ìsìn wọn bí ọ̀mùtí.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan