Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Isaiah 35 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ayọ̀ àwọn ẹni ìràpadà

1 Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn; aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná. Gẹ́gẹ́ bí ewéko,

2 Ní títanná yóò tanná; yóò yọ ayọ̀ ńláńlá yóò sì kọrin. Ògo Lebanoni ni a ó fi fún un, ẹwà Karmeli àti Ṣaroni; wọn yóò rí ògo Olúwa, àti ẹwà Ọlọ́run wa.

3 Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun:

4 Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.”

5 Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́.

6 Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.

7 Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà, ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Ní ibùgbé àwọn dragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi.

8 Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà Ìwà Mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà, àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá.

9 Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀,

10 àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan