Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Isaiah 24 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ìparun Olúwa lórí ilẹ̀ ayé

1 Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—

2 bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbèsè.

3 Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

4 Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú

5 àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́; wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.

6 Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.

7 Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ, gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.

8 Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́ ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.

9 Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.

10 Ìlú tí a run ti dahoro, ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.

11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́, gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro, ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.

13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán.

14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀; láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo ọláńlá Olúwa.

15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa; gbé orúkọ Olúwa ga, àní Ọlọ́run Israẹli, ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun,

16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin; “Ògo ni fún olódodo n nì.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé! “Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”

17 Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́, ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.

18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà yóò ṣubú sínú ihò, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú. Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀ Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.

19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.

20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́; Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.

21 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.

22 A ó sì kó wọn jọ pọ̀, gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò, a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú, a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

23 A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn; nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu, àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan