Isaiah 15 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníÀsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu 1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu: A pa Ari run ní Moabu, òru kan ní a pa á run! A pa Kiri run ní Moabu, òru kan ní a pa á run! 2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún, Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù. 3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú. Wọ́n pohùnréré Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún. 4 Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì. 5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari, títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi. Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ, Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn 6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́. 7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari. 8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu; ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu, igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu. 9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni— kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.