Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Hosea 8 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Israẹli yípadà kúrò ní ọnà

1 “Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.

2 Israẹli kígbe pè mí ‘Háà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’

3 Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀

4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, si ìparun ara wọn.

5 Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria! Ìbínú mi ń ru sí wọn: yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?

6 Israẹli ni wọ́n ti wá! Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é Àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.

7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àjèjì ni yóò jẹ.

8 A ti gbé Israẹli mì, báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè bí ohun èlò tí kò wúlò.

9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri. Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín orílẹ̀-èdè Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.

11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un

12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn. Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì

13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀ Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn. Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọn yóò padà sí Ejibiti

14 Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan