Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Hosea 11 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ìfẹ́ Ọlọ́run sí Israẹli

1 “Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.

2 Bí a ti ń pe wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi, wọn rú ẹbọ sí Baali, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.

3 Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn láradá.

4 Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.

5 “Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?

6 Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.

7 Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ, kò ní gbé wọn ga rárá.

8 “Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣeboimu? Ọkàn mi yípadà nínú mi àánú mi sì ru sókè

9 Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ, tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro. Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrín yín, Èmi kò ní í wá nínú ìbínú

10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún Nígbà tó bá bú àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.

11 Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bí i ẹyẹ láti Ejibiti bí i àdàbà láti Asiria Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni Olúwa wí.


Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli

12 Efraimu tí fi irọ́ yí mi ká ilé Israẹli pẹ̀lú ẹ̀tàn. Ṣùgbọ́n Juda sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run Ó sì ṣe olóòtítọ́ sí Ẹni mímọ́ Israẹli.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan