Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Heberu 5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀.

2 Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú.

3 Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà.

4 Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.

5 Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.”

6 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibòmíràn pé, “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

7 Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.

8 Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀;

9 Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀:

10 Tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.


Ìkìlọ̀ lórí ṣíṣubú kúrò nínú ìgbàgbọ́

11 Nípa èyí àwa ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́.

12 Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ni, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle.

13 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń mu wàrà jẹ́ aláìlóye ọ̀rọ̀ òdodo: nítorí ọmọ ọwọ́ ni.

14 Ṣùgbọ́n oúnjẹ líle wà fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọn ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàrín rere àti búburú.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan