Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

1 Kronika 14 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Ilé àti ìdílé Dafidi

1 Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un.

2 Dafidi sì mọ Israẹli àti pé Olúwa ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀.

3 Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin.

4 Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni,

5 Ibhari, Eliṣua, Elifeleti,

6 Noga, Nefegi, Jafia,

7 Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti.


Dafidi ṣẹ́gun àwọn ará Filistini

8 Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi ààmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn.

9 Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti Àfonífojì Refaimu;

10 Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé: “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” Olúwa sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.”

11 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu.

12 Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná.

13 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì,

14 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi.

15 Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini.

16 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri.

17 Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, Olúwa sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan