Titu 2 - Bibeli MimọẸ̀kọ́ tí ó Yè Kooro 1 ṢUGBỌN iwọ mã sọ ohun ti o yẹ si ẹkọ́ ti o yè kõro: 2 Ki awọn àgba ọkunrin jẹ ẹni iwọntunwọnsin, ẹni-ọ̀wọ, alairekọja, ẹniti o yè kõro ni igbagbọ́, ni ifẹ, ni sũru. 3 Bẹ̃ gẹgẹ ni ki awọn agba obinrin jẹ ẹni-ọ̀wọ ni iwa, ki nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin, tabi ọmuti, bikoṣe olukọni ni ohun rere; 4 Ki nwọn ki o le tọ́ awọn ọdọmọbirin lati fẹran awọn ọkọ wọn, lati fẹran awọn ọmọ wọn, 5 Lati jẹ alairekọja, mimọ́, òṣiṣẹ́ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun ki o máṣe di isọ̀rọ-òdi si. 6 Bẹ̃ gẹgẹ ni ki o gbà awọn ọdọmọkunrin niyanju lati jẹ alairekọja. 7 Ninu ohun gbogbo mã fi ara rẹ hàn li apẹrẹ iṣẹ rere: ninu ẹkọ́ mã fi aiṣebajẹ hàn, ìwa àgba, 8 Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa. 9 Gbà awọn ọmọ-ọdọ niyanju lati mã tẹriba fun awọn oluwa wọn, ki nwọn ki o mã ṣe ohun ti o wu wọn ninu ohun gbogbo; ki nwọn ki o má gbó wọn lohùn; 10 Ki nwọn ki o máṣe irẹjẹ, ṣugbọn ki nwọn ki o mã fi iwa otitọ rere gbogbo han; ki nwọn ki o le mã ṣe ẹkọ́ Ọlọrun Olugbala wa li ọṣọ́ ninu ohun gbogbo. 11 Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan, 12 O nkọ́ wa pe, ki a sẹ́ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mã wà li airekọja, li ododo, ati ni ìwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi; 13 Ki a mã wo ọna fun ireti ti o ni ibukún ati ifarahan ogo Ọlọrun wa ti o tobi, ati ti Olugbala wa Jesu Kristi; 14 Ẹniti o fi ara rẹ̀ fun wa, ki on ki o le rà wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ gbogbo, ki o si le wẹ awọn enia kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ini on tíkararẹ awọn onitara iṣẹ rere. 15 Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o mã sọ, ki o si ma gbà-ni-niyanju, ki o si mã fi aṣẹ gbogbo ba-ni-wi. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ọ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria