Romu 4 - Bibeli MimọÀpẹẹrẹ Abrahamu 1 NJẸ kili awa o ha wipe Abrahamu, baba wa nipa ti ara, ri? 2 Nitori bi a ba da Abrahamu lare nipa iṣẹ, o ni ohun iṣogo; ṣugbọn kì iṣe niwaju Ọlọrun. 3 Iwe-mimọ́ ha ti wi? Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u. 4 Njẹ fun ẹniti o ṣiṣẹ a kò kà ère na si ore-ọfẹ bikoṣe si gbese. 5 Ṣugbọn fun ẹniti kò ṣiṣẹ, ti o si ngbà ẹniti o nda enia buburu lare gbọ́, a kà igbagbọ́ rẹ̀ si ododo. 6 Gẹgẹ bi Dafidi pẹlu ti pe oluwarẹ̀ na ni ẹni ibukun, ẹniti Ọlọrun kà ododo si laisi ti iṣẹ́, 7 Wipe, Ibukún ni fun awọn ẹniti a dari irekọja wọn jì, ti a si bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ. 8 Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si li ọrùn. 9 Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo. 10 Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni. 11 O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu: 12 Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla. Ìlérí Ṣẹ Nípa Igbagbọ 13 Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́. 14 Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara: 15 Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀. 16 Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa, 17 (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà; 18 Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri. 19 Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara: 20 Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; 21 Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e. 22 Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u. 23 A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u, 24 Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú; 25 Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria