Romu 3 - Bibeli Mimọ1 NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ? 2 Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ. 3 Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi? 4 Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ. 5 Ṣugbọn bi aiṣododo wa ba nyìn ododo Ọlọrun, kili awa o wi? Ọlọrun ti nfi ibinu rẹ̀ han ha ṣe alaiṣododo bi? (Mo fi ṣe akawe bi enia.) 6 Ki a má ri: bi bẹ̃ni, Ọlọrun yio ha ṣe le dajọ araiye? 7 Nitori bi otitọ Ọlọrun ba di pipọ si iyìn rẹ̀ nitori eke mi, ẽṣe ti a fi nda mi lẹjọ bi ẹlẹṣẹ mọ́ si? 8 Ẽṣe ti a kò si wipe (gẹgẹ bi a ti nsọrọ wa ni ibi, ati gẹgẹ bi awọn kan ti nsọ pe, awa nwipe,) Ẹ jẹ ki a mã ṣe buburu, ki rere ki o le jade wá? awọn ẹniti ẹ̀bi wọn tọ́. Kò Sí Olódodo Kan 9 Njẹ ki ha ni? awa ha san jù wọn bi? Kò ri bẹ̃ rara: nitori a ti fihan ṣaju pe ati awọn Ju ati awọn Hellene, gbogbo nwọn li o wà labẹ ẹ̀ṣẹ; 10 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: 11 Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. 12 Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan. 13 Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: 14 Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: 15 Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: 16 Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: 17 Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: 18 Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn. 19 Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun. 20 Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá. Ìdáláre Nípa Igbagbọ 21 Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli; 22 Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ: 23 Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; 24 Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: 25 Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun; 26 Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́. 27 Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́. 28 Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin. 29 Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu: 30 Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn. 31 Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria