Romu 2 - Bibeli MimọÌdájọ́ Òdodo Tí Ọlọrun Ṣe 1 NITORINA alairiwi ni iwọ ọkunrin na, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ ti ndajọ: nitori ninu ohun ti iwọ nṣe idajọ ẹlomiran, iwọ ndá ara rẹ lẹbi; nitori iwọ ti ndajọ nṣe ohun kanna. 2 Ṣugbọn awa mọ̀ pe idajọ Ọlọrun jẹ gẹgẹ bi otitọ si gbogbo awọn ti o nṣe irú ohun bawọnni. 3 Ati iwọ ọkunrin na ti nṣe idajọ awọn ti nṣe irú ohun bawọnni, ti iwọ si nṣe bẹ̃ na, iwọ ro eyi pe iwọ ó yọ ninu idajọ Ọlọrun? 4 Tabi iwọ ngàn ọrọ̀ ore ati ipamọra ati sũru rẹ̀, li aimọ̀ pe ore Ọlọrun li o nfà ọ lọ si ironupiwada? 5 Ṣugbọn gẹgẹ bi lile ati aironupiwada ọkàn rẹ, ni iwọ nfi ibinu ṣura fun ara rẹ de ọjọ ibinu ati ti ifihàn idajọ ododo Ọlọrun: 6 Ẹniti yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: 7 Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun; 8 Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà. 9 Ipọnju ati irora, lori olukuluku ọkàn enia ti nhuwa ibi, ti Ju ṣaju, ati ti Hellene pẹlu; 10 Ṣugbọn ogo, ati ọlá, ati alafia, fun olukuluku ẹni ti nhuwa rere, fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu: 11 Nitori ojuṣaju enia kò si lọdọ Ọlọrun. 12 Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ; 13 Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare. 14 Nitori nigbati awọn Keferi, ti kò li ofin, ba ṣe ohun ti o wà ninu ofin nipa ẹda, awọn wọnyi ti kò li ofin, jẹ ofin fun ara wọn: 15 Awọn ẹniti o fihan pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn li ọkàn, ti ọkàn wọn si njẹ wọn lẹri, ti iro wọn larin ara wọn si nfi wọn sùn tabi ti o ngbè wọn, 16 Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi. Àwọn Juu ati Òfin 17 Ṣugbọn bi a ba npè iwọ ni Ju, ti o si simi le ofin, ti o si nṣogo ninu Ọlọrun, 18 Ti o si mọ̀ ifẹ rẹ̀, ti o si dán ohun ti o yàtọ wò, ẹniti a ti kọ li ofin; 19 Ti o si gbé oju le ara rẹ̀ pe iwọ li amọ̀na awọn afọju, imọlẹ awọn ti o wà li òkunkun, 20 Olukọ awọn alaimoye, olukọ awọn ọmọde, ẹniti o ni afarawe imọ ati otitọ ofin li ọwọ. 21 Njẹ iwọ ti o nkọ́ ẹlomiran, iwọ kò kọ́ ara rẹ? iwọ ti o nwasu ki enia ki o má jale, iwọ njale? 22 Iwọ ti o nwipe ki enia ki o máṣe panṣaga, iwọ nṣe panṣaga? iwọ ti o ṣe họ̃ si oriṣa, iwọ njà tẹmpili li ole? 23 Iwọ ti nṣogo ninu ofin, ni riru ofin iwọ bù Ọlọrun li ọlá kù? 24 Nitori orukọ Ọlọrun sá di isọrọ-buburu si ninu awọn Keferi nitori nyin, gẹgẹ bi a ti kọ ọ. 25 Nitori ikọla li ère lõtọ, bi iwọ ba pa ofin mọ́: ṣugbọn bi iwọ ba jẹ arufin, ikọla rẹ di aikọla. 26 Nitorina bi alaikọla ba pa ilana ofin mọ́, a kì yio ha kà aikọla rẹ̀ si ikọla bi? 27 Alaikọla nipa ti ẹda, bi o ba pa ofin mọ́, kì yio ha da ẹbi fun iwọ ti o jẹ arufin nipa ti iwe ati ikọla? 28 Kì iṣe eyi ti o farahan ni Ju, bẹni kì iṣe eyi ti o farahan li ara ni ikọla: 29 Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria