O. Sol 8 - Bibeli Mimọ1 IWỌ iba jẹ dabi arakunrin fun mi, ti o mu ọmú iya mi! emi iba ri ọ lode emi iba fi ẹnu kò ọ lẹnu; lõtọ, nwọn kì ba fi mi ṣe ẹlẹya. 2 Emi iba fọnahàn ọ, emi iba mu ọ wá sinu ile iya mi, iwọ iba kọ́ mi: emi iba mu ọ mu ọti-waini õrùn didùn, ati oje eso granate mi. 3 Ọwọ osì rẹ̀ iba wà labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ iba si gbá mi mọra. 4 Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ṣe ji i, titi yio fi wù u. 5 Tani eyi ti ngòke lati aginju wá, ti o fi ara tì olufẹ rẹ̀? mo ji ọ dide labẹ igi eleso: nibẹ ni iya rẹ gbe bi ọ si, nibẹ li ẹniti o bi ọ gbe bi ọ si. 6 Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa. 7 Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata. 8 Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ? 9 Bi on ba ṣe ogiri, awa o kọ́ ile-odi fadaka le e lori: bi on ba si ṣe ẹnu-ọ̀na, awa o fi apako kedari dí i. 10 Ogiri ni mi, ọmú mi sì dabi ile-iṣọ: nigbana loju rẹ̀ mo dabi ẹniti o ri alafia. 11 Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀. 12 Ọgba-àjara mi, ti iṣe temi, o wà niwaju mi: iwọ Solomoni yio ni ẹgbẹrun fadaka, ati awọn ti nṣọ eso na yio ni igba. 13 Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu. 14 Yara, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin tabi ọmọ agbọnrin lori òke õrùn didùn. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria