O. Sol 7 - Bibeli Mimọ1 Ẹsẹ rẹ ti li ẹwà to ninu bata, iwọ ọmọ-alade! orike itan rẹ dabi ohun ọṣọ́, iṣẹ ọwọ ọlọgbọ́n oniṣọna. 2 Iwọ́ rẹ dabi ago ti kò ṣe alaini ọti, ara rẹ dabi okiti alikama ti a fi lili yika. 3 Ọmú rẹ mejeji dabi abo ọmọ agbọnrin meji ti iṣe ìbejì. 4 Ọrùn rẹ dabi ile iṣọ ehin-erin; oju rẹ dabi adagun ni Heṣboni, lẹba ẹnu-bode Batrabbimu: imú rẹ dabi ile-iṣọ Lebanoni ti o kọju si ihà Damasku. 5 Ori rẹ dabi Karmeli lara rẹ, ati irun ori rẹ bi purpili; a fi aidì irun rẹ di ọba mu. 6 O ti li ẹwà to, o si ti dara to, iwọ olufẹ mi ninu adùn ifẹ! 7 Iduro rẹ yi dabi igi ọ̀pẹ ati ọmú rẹ bi ṣiri eso àjara. 8 Mo ni, emi o gùn ọ̀pẹ lọ, emi o di ẹka rẹ̀ mu: pẹlupẹlu nisisiyi ọmú rẹ pẹlu yio dabi ṣiri àjara, ati õrùn imú rẹ bi eso appili; 9 Ati ẹnu rẹ bi ọti-waini ti o dara jù, ti o sọkalẹ kẹlẹkẹlẹ fun olufẹ mi, ti o nmu ki etè awọn ti o sùn ki o sọ̀rọ. 10 Ti olufẹ mi li emi iṣe, ifẹ rẹ̀ si mbẹ si mi. 11 Wá, olufẹ mi, jẹ ki a lọ si pápa; jẹ ki a wọ̀ si iletò wọnni. 12 Jẹ ki a dide lọ sinu ọgba-àjara ni kutukutu; jẹ ki a wò bi àjara ruwe, bi itanná àjara ba là, ati bi igi granate ba rudi: nibẹ li emi o fi ifẹ mi fun ọ. 13 Awọn eso mandraki fun ni li õrùn, li ẹnu-ọ̀na wa ni onirũru eso ti o wunni, ọtun ati ogbologbo, ti mo ti fi pamọ́ fun ọ, iwọ olufẹ mi. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria