O. Sol 6 - Bibeli Mimọ1 NIBO ni olufẹ rẹ lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? nibo li olufẹ rẹ yà si? ki a le ba ọ wá a. 2 Olufẹ mi sọkalẹ lọ sinu ọgba rẹ̀, si ebè turari, lati ma jẹ̀ ninu ọgbà, ati lati ká itanna lili. 3 Emi ni ti olufẹ mi, olufẹ mi si ni ti emi: o njẹ̀ lãrin itanna lili. Orin Karun-un 4 Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalemu, ṣugbọn o li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun. 5 Mu oju rẹ kuro lara mi nitori nwọn bori mi: irun rẹ si dabi ọwọ́ ewurẹ ti o dubulẹ ni Gileadi. 6 Ehin rẹ dabi ọwọ́ agutan ti ngòke lati ibi iwẹ̀ wá, ti olukuluku wọn bi ìbejì, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn. 7 Bi ẹ̀la eso-pomegranate kan ni ẹrẹkẹ rẹ ri lãrin iboju rẹ. 8 Ọgọta ayaba ni mbẹ, ati ọgọrin àle, ati awọn wundia lainiye. 9 Ọkan ni adaba mi, alailabawọn mi; on nikanṣoṣo ni ti iya rẹ̀, on ni ãyo ẹniti o bi i. Awọn ọmọbinrin ri i, nwọn si sure fun u; ani awọn ayaba ati awọn àle, nwọn si yìn i. 10 Tali ẹniti ntàn jàde bi owurọ, ti o li ẹwà bi oṣupa, ti o mọ́ bi õrun, ti o si li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun? 11 Emi sọkalẹ lọ sinu ọgba eso igi, lati ri awọn ẹka igi tutu afonifoji, ati lati ri bi ajara ba ruwe, ati bi igi-granate ba rudi. 12 Ki emi to mọ̀, ọkàn mi gbe mi ka ori kẹkẹ́ Amminadibu. 13 Pada, pada, Ṣulamite; pada, pada, ki awa ki o le wò ọ. Ẽṣe ti ẹnyin fẹ wò Ṣulamite bi ẹnipe orin ijó Mahanaimu. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria