O. Sol 5 - Bibeli Mimọ1 MO de inu ọgbà mi, arabinrin mi, iyawo! mo ti kó ojia mi pẹlu õrùn didùn mi jọ; mo ti jẹ afara mi pẹlu oyin mi; mo ti mu ọti-waini mi pẹlu wàra mi: Ẹ jẹun, ẹnyin ọrẹ́; mu, ani mu amuyo, ẹnyin olufẹ. Orin Kẹrin 2 Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru. 3 Mo ti bọ́ awọtẹlẹ mi; emi o ti ṣe gbe e wọ̀? mo ti wẹ̀ ẹsẹ̀ mi; emi o ti ṣe sọ wọn di aimọ́? 4 Olufẹ mi nawọ rẹ̀ lati inu ihò ilẹkùn, inu mi sì yọ si i. 5 Emi dide lati ṣilẹkun fun olufẹ mi, ojia si nkán lọwọ mi, ati ojia olõrùn didùn ni ika mi sori idimu iṣikà. 6 Mo ṣilẹkun fun olufẹ mi; ṣugbọn olufẹ mi ti fà sẹhin, o si ti lọ: aiya pá mi nigbati o sọ̀rọ, mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i, mo pè e, ṣugbọn on kò da mi lohùn. 7 Awọn oluṣọ ti nrìn ilu kiri ri mi, nwọn lù mi, nwọn sì ṣa mi lọgbẹ, awọn oluṣọ gbà iborùn mi lọwọ mi. 8 Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi ẹnyin ba ri olufẹ mi, ki ẹ wi fun u pe, aisan ifẹ nṣe mi. 9 Kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? kini olufẹ rẹ jù olufẹ miran ti iwọ fi nfi wa bú bẹ̃? 10 Olufẹ mi funfun, o si pọn, on ni ọlá jù ọ̀pọlọpọ lọ. 11 Ori rẹ̀ dabi wura ti o dara julọ, ìdi irun rẹ̀ dabi imọ̀ ọpẹ, o si du bi ẹiyẹ iwò. 12 Oju rẹ̀ dabi àdaba li ẹba odò, ti a fi wàra wẹ̀, ti o si ngbe inu alafia. 13 Ẹrẹ̀kẹ rẹ̀ dabi ebè turari, bi olõrùn didùn, ète rẹ̀ bi itanna lili, o nkán ojia olõrùn didùn. 14 Ọwọ rẹ̀ dabi oruka wura ti o tò ni berili yika, ara rẹ̀ bi ehin-erin didán ti a fi saffire bò. 15 Itan rẹ̀ bi ọwọ̀n marbili, ti a gbe ka ihò ìtẹbọ wura daradara; ìwo rẹ̀ dabi Lebanoni, titayọ rẹ̀ bi igi kedari. 16 Ẹnu rẹ̀ dùn rekọja: ani o wunni patapata. Eyi li olufẹ mi, eyi si li ọrẹ mi, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria