Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 99 - Bibeli Mimọ


Ọlọrun Ọba Atóbijù

1 OLUWA jọba; jẹ ki awọn enia ki o wariri: o joko lori awọn kerubu; ki aiye ki o ta gbọ̀ngbọ́n.

2 Oluwa tobi ni Sioni: o si ga jù gbogbo orilẹ-ède lọ.

3 Ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru; mimọ́ li on.

4 Agbara ọba fẹ idajọ pẹlu, iwọ fi idi aiṣegbe mulẹ; iwọ nṣe idajọ ati ododo ni Jakobu.

5 Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ̀: mimọ́ li on.

6 Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ̀, ati Samueli ninu awọn ti npè orukọ rẹ̀: nwọn ke pè Oluwa, o si da wọn lohùn.

7 O ba wọn sọ̀rọ ninu ọwọ̀n awọsanma: nwọn pa ẹri rẹ̀ mọ́ ati ilana ti o fi fun wọn.

8 Iwọ da wọn lohùn, Oluwa Ọlọrun wa: iwọ li Ọlọrun ti o dariji wọn, ti o si san ẹsan iṣẹ wọn.

9 Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sìn nibi òke mimọ́ rẹ̀; nitori Oluwa Ọlọrun wa mimọ́ ni.

Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan