O. Daf 98 - Bibeli MimọỌlọrun, Ọba gbogbo Ayé 1 Ẹ kọrin titun si Oluwa; nitoriti o ti ṣe ohun iyanu: ọwọ ọtún rẹ̀, ati apa rẹ̀ mimọ́ li o ti mu igbala wa fun ara rẹ̀. 2 Oluwa ti sọ igbala rẹ̀ di mimọ̀: ododo rẹ̀ li o ti fi hàn nigbangba li ojú awọn keferi. 3 O ti ranti ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ si awọn ara ile Israeli: gbogbo opin aiye ti ri igbala Ọlọrun wa. 4 Ẹ ho iho ayọ̀ si Oluwa, gbogbo aiye: ẹ ho yè, ẹ yọ̀, ki ẹ si ma kọrin iyìn. 5 Ẹ ma fi duru kọrin si Oluwa, ati duru pẹlu ohùn orin-mimọ́. 6 Pẹlu ipè ati ohùn fere, ẹ ho iho ayọ̀ niwaju Oluwa, Ọba. 7 Jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀; aiye, ati awọn ti mbẹ ninu rẹ̀. 8 Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ̀. 9 Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria