O. Daf 97 - Bibeli MimọỌlọrun Ọba Atóbijù 1 OLUWA jọba; ki aiye ki o yọ̀; jẹ ki inu ọ̀pọlọpọ erekuṣu ki o dùn. 2 Awọsanma ati okunkun yi i ka: ododo ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ̀. 3 Iná ṣaju rẹ̀, o si jo awọn ọta rẹ̀ yika kiri. 4 Manamana rẹ̀ kọ imọlẹ si aiye: aiye ri i, o si wariri. 5 Awọn òke nyọ́ bi ida niwaju Oluwa, niwaju Oluwa gbogbo aiye: 6 Ọrun fi ododo rẹ̀ hàn, gbogbo orilẹ-ède si ri ogo rẹ̀. 7 Oju yio tì gbogbo awọn ti nsìn ere fifin, ẹniti nfi ere ṣe ileri ara wọn: ẹ ma sìn i, gbogbo ẹnyin ọlọrun. 8 Sioni gbọ́, inu rẹ̀ si dùn; awọn ọmọbinrin Juda si yọ̀, Oluwa, nitori idajọ rẹ. 9 Nitoripe Iwọ Oluwa, li o ga jù gbogbo aiye lọ: Iwọ li a gbé ga jù gbogbo oriṣa lọ. 10 Ẹnyin ti o fẹ Oluwa, ẹ korira ibi: o pa ọkàn awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́: o gbà wọn li ọwọ awọn enia buburu. 11 A funrugbin imọlẹ fun olododo, ati inu didùn fun alaiya diduro. 12 Ẹ yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo; ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria