O. Daf 96 - Bibeli MimọỌlọrun Ọba Àwọn Ọba 1 Ẹ kọrin titun si Oluwa: ẹ kọrin si Oluwa gbogbo aiye. 2 Ẹ kọrin si Oluwa, fi ibukún fun orukọ rẹ̀; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. 3 Sọ̀rọ ogo rẹ̀ lãrin awọn keferi, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ lãrin gbogbo enia. 4 Nitori ti Oluwa tobi, o si ni iyìn pupọ̀pupọ̀: on li o ni ìbẹru jù gbogbo oriṣa lọ. 5 Nitori pe gbogbo oriṣa orilẹ-ède asan ni nwọn: ṣugbọn Oluwa li o da ọrun. 6 Ọlá ati ọla-nla li o wà niwaju rẹ̀: ipa ati ẹwà mbẹ ninu ibi mimọ́ rẹ̀. 7 Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipá fun Oluwa. 8 Ẹ fi ogo fun orukọ Oluwa: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ̀. 9 Ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́: ẹ wariri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye. 10 Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, Oluwa jọba: nitõtọ a o fi idi aiye mulẹ ti kì yio le yẹ̀: on o fi ododo ṣe idajọ enia. 11 Jẹ ki ọrun ki o yọ̀, jẹ ki inu aiye ki o dùn; jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀. 12 Jẹ ki oko ki o kún fun ayọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: nigbana ni gbogbo igi igbo yio ma yọ̀. 13 Niwaju Oluwa: nitoriti mbọwa, nitori ti mbọwa ṣe idajọ aiye: yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rẹ̀ ṣe. |
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.
Bible Society of Nigeria